Numbers 28:17-25

17 aNí ọjọ́ kẹ́ẹ̀dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà. 18Ní ọjọ́ kìn-ín-ní kí àpéjọ mímọ́ kí ó wà; ẹ́yin kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ agbára kankan. 19Ẹ rú ẹbọ sísun sí Olúwa, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́-àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù. 20Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá; 21pẹ̀lú ọ̀dọ́-àgùntàn kọ̀ọ̀kan ìdákan nínú mẹ́wàá. 22Pẹ̀lú òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún un yín. 23Ṣe eléyìí ní àfikún sí ẹbọ sísun àràárọ̀. 24Báyìí ní kí ẹ̀yin rúbọ ní ọjọọjọ́, jálẹ̀ ní ọjọ́ méjèèje, oúnjẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, tí olóòórùn dídùn sí Olúwa; ó rú u pẹ̀lú ẹbọ sísun ìgbà gbogbo, àti ẹbọ ohun mímu. 25Ní ọjọ́ keje kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan.

Copyright information for YorBMYO